Lefitiku 15:30-33
30
Kí àlùfáà fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún un, níwájú Olúwa fún àìmọ́ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
31
“ ‘Ẹ ya ará Israẹli sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun tí ó ń sọ wọ́n di aláìmọ́, kí wọ́n má bá a kú nínú àìmọ́ wọn nípa bíba ibùgbé mímọ́ mi jẹ́, èyí tí ó wà láàrín wọn.’ ”
32
Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ọkùnrin tí ó ni ìsunjáde fún ẹnikẹ́ni tí a sọ di àìmọ́ nípa ìsunjáde nǹkan ọkùnrin rẹ̀.
33
Fún obìnrin ní nǹkan oṣù rẹ̀, fún ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ní ìsunjáde, àti fún ọkùnrin tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin tí ó jẹ́ aláìmọ́.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings