Ẹkún Jeremiah 3:55-66
55
Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa, láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.
56
Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”
57
O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”
58
Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà.
59
O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi. Gba ẹjọ́ mi ró!
60
Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn, gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.
61
Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi,
62
ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ sí mi ní gbogbo ọjọ́.
63
Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde, wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.
64
Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.
65
Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn, kí o sì fi wọ́n ré.
66
Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú, lábẹ́ ọ̀run Olúwa.
Settings