Onidajọ 5:12-18
12
‘Jí, jí, Debora! Jí, jí, kọ orin dìde! Dìde ìwọ Baraki! Kó àwọn ìgbèkùn rẹ ní ìgbèkùn ìwọ ọmọ Abinoamu.’
13
“Nígbà náà ni àwọn tókù sọ̀kalẹ̀ àwọn ọlọ́lá lọ; àwọn ènìyàn Olúwa tọ̀ mí wá pẹ̀lú àwọn alágbára.
14
Àwọn kan jáde wá láti Efraimu, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Amaleki; Benjamini wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ. Láti Makiri ni àwọn aláṣẹ ti sọ̀kalẹ̀ wá, láti Sebuluni ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́.
15
Àwọn ọmọ-aládé Isakari wá pẹ̀lú Debora; bí Isakari ti ṣe olóòtítọ́ sí Baraki, wọ́n fi ẹsẹ̀ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà. Ní ipadò Reubeni ni ìgbèrò púpọ̀ wà.
16
Èéṣe tí ìwọ fi dúró pẹ́ láàrín agbo àgùntàn láti máa gbọ́ fèrè olùṣọ́-àgùntàn? Ní ipadò Reubeni ni ìgbèrò púpọ̀ wà.
17
Gileadi dúró ní òkè odò Jordani. Èéṣe tí Dani fi dúró nínú ọkọ̀ ojú omi? Aṣeri jókòó ní etí bèbè Òkun, ó sì ń gbé èbúté rẹ̀.
18
Àwọn ènìyàn Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú; bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Naftali ní ibi gíga pápá.
Settings