Onidajọ 3:31
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 31 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
28
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Moabu ọ̀tá yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jordani tí ó lọ sí ilẹ̀ Moabu, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá.
29
Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin ará Moabu tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà.
30
Ní ọjọ́ náà ni Israẹli ṣẹ́gun àwọn ará Moabu, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún.
31
Lẹ́yìn Ehudu, ni Ṣamgari ọmọ Anati ẹni tí ó pa ẹgbẹ̀ta (600) Filistini pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Israẹli kúrò nínú ìpọ́njú.
Settings