Onidajọ 14:15-18
15
Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Samsoni, pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná. Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòṣì tàbí kó wa lẹ́rú ni?”
16
Nígbà náà ni ìyàwó Samsoni ṣubú lé e láyà, ó sì sọkún ní iwájú rẹ̀ pé, “O kórìíra mi! O kò sì ní ìfẹ́ mi nítòótọ́, o pàlọ́ fún àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.” “Èmi kò tí ì ṣe àlàyé rẹ̀ fún baba àti ìyá mi, báwo ni èmi ó ṣe sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”
17
Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sọkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀.
18
Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé, “Kí ni ó dùn ju oyin lọ? Kí ni ó sì lágbára ju kìnnìún lọ?” Samsoni dá wọn lóhùn pé, “Bí kì í bá ṣe pé ẹ fi ọ̀dọ́ abo màlúù mi kọ ilẹ̀, ẹ̀yin kò bá tí mọ ìtumọ̀ sí àlọ́ mi.”
Settings