Skip to content
Johanu 5:31-47

Johanu 5:31-47

31
“Bí èmi bá ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òtítọ́.
32
Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi; èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi tí ó jẹ́.
33
“Ẹ̀yin ti ránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Johanu, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́.
34
Ṣùgbọ́n èmi kò gba ẹ̀rí lọ́dọ̀ ènìyàn, nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là.
35
Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀, ẹ̀yin sì fẹ́ fún sá à kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.
36
“Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀jù ti Johanu lọ. Nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rìí mi pé, Baba ni ó rán mi.
37
Àti Baba tìkára rẹ̀ tí ó rán mi ti jẹ́rìí mi. Ẹ̀yin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò rí ìrísí rẹ̀.
38
Ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti máa gbé inú yín, nítorí ẹni tí ó rán, òun ni ẹ̀yin kò gbàgbọ́.
39
Ẹ̀yin ń wá ìwé mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rìí mi.
40
Ẹ̀yin kò sì fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ba à lè ní ìyè.
41
“Èmi kò gba ògo lọ́dọ̀ ènìyàn.
42
Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé, ẹ̀yin fúnra yín kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín.
43
Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò sì gbà mí; bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, òun ni ẹ̀yin yóò gbà.
44
Ẹ̀yin ó ti ṣe lè gbàgbọ́, ẹ̀yin tí ń gba ògo lọ́dọ̀ ara yín tí kò wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan wá?
45
“Ẹ má ṣe rò pé, èmi ó fi yín sùn lọ́dọ̀ Baba, ẹni tí ń fi yín sùn wà, àní Mose, ẹni tí ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé.
46
Nítorí pé ẹ̀yin ìbá gba Mose gbọ́, ẹ̀yin ìbá gbà mí gbọ́, nítorí ó kọ ìwé nípa tèmi.
47
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gba ìwé rẹ̀ gbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbà ọ̀rọ̀ mi gbọ́?”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options