Johanu 16:29-33
29
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Wò ó, nígbà yìí ni ìwọ ń sọ̀rọ̀ gbangba, ìwọ kò sì sọ ohunkóhun ní òwe.
30
Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè: nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá.”
31
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ wàyí?
32
Kíyèsi i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi.
33
“Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”
Settings