Johanu 15:18
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 18 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
15
Èmi kò pè yín ní ọmọ ọ̀dọ̀ mọ́; nítorí ọmọ ọ̀dọ̀ kò mọ ohun tí olúwa rẹ̀ ń ṣe, ṣùgbọ́n èmi pè yín ní ọ̀rẹ́ nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, mo ti fihàn fún yín.
16
Kì í ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì fi yín sípò, kí ẹ̀yin kí ó lè lọ, kí ẹ sì so èso, àti kí èso yín lè dúró; kí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín.
17
Nǹkan wọ̀nyí ni mo pàṣẹ fún yín pé, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín.
18
“Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé, ó ti kórìíra mi ṣáájú yín.
19
Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ń ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ yin bi àwọn tirẹ̀; gẹ́gẹ́ bi o ṣe ri tí ẹ̀yin kì ń ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n èmi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín.
20
Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín pé, ‘Ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju olúwa rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú: bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n ó sì pa tiyín mọ́ pẹ̀lú.
21
Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n yóò ṣe sí yín, nítorí orúkọ mi, nítorí tí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi.
Settings