Jobu 9:14-20
14
“Kí ní ṣe tí èmi ti n o fi ba ṣàròyé? Tí èmi yóò fi ma ṣe àwáwí?
15
Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn; ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú.
16
Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.
17
Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá, ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí.
18
Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.
19
Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó! Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò?
20
Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi; bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.
Settings