Jobu 38:4-11
4
“Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye.
5
Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?
6
Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,
7
nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?
8
“Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkun mọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá.
9
Nígbà tí mo fi àwọsánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri ṣe ọ̀já ìgbà inú rẹ̀.
10
Nígbà tí mo ti pàṣẹ ìpinnu mi fún un, tí mo sì ṣe bèbè àti ìlẹ̀kùn.
11
Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?
Settings