Skip to content
Jobu 22:12-20

Jobu 22:12-20

12
“Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run? Sá wo orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!
13
Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀? Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?
14
Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ tí ó nípọn jẹ ìbora fún un, tí kò fi lè ríran; ó sì ń rìn nínú àyíká ọ̀run.
15
Ǹjẹ́ ìwọ fẹ́ rin ipa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọn ènìyàn búburú tí rìn?
16
A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayé láìpé ọjọ́ wọn, ìpìlẹ̀ wọn ti da bí odò ṣíṣàn.
17
Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa! Kí ni Olódùmarè yóò ṣe fún wọn?’
18
Síbẹ̀ ó fi ohun rere kún ilé wọn! Ṣùgbọ́n ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi!
19
Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀, àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà pé,
20
‘Lóòtítọ́ àwọn ọ̀tá wa ni a ké kúrò, iná yóò sì jó oró wọn run.’
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options