Skip to content
Jeremiah 51:25-33

Jeremiah 51:25-33

25
“Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirun ìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,” ni Olúwa wí. “Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ, èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta, Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó.
26
A kò ní mú òkúta kankan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbí fún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò di ahoro títí ayé,” ní Olúwa wí.
27
“Gbé àsíá sókè ní ilẹ̀ náà! Fọn ìpè láàrín àwọn orílẹ̀-èdè! Sọ àwọn orílẹ̀-èdè di mímọ́ sórí rẹ̀, pe àwọn ìjọba yìí láti dojúkọ ọ́: Ararati, Minini àti Aṣkenasi. Yan olùdarí ogun láti kọlù ú, rán àwọn ẹṣin sí i bí ọ̀pọ̀ eṣú.
28
Sọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú àwọn ọba Media di mímọ́ sórí rẹ̀, àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ ọba lé lórí.
29
Ilẹ̀ wárìrì síyìn-ín sọ́hùn-ún, nítorí pé ète Olúwa, sí Babeli dúró, láti ba ilẹ̀ Babeli jẹ́ lọ́nà tí ẹnikẹ́ni kò ní lè gbé inú rẹ̀ mọ́.
30
Gbogbo àwọn jagunjagun Babeli tó dáwọ́ ìjà dúró sínú àgọ́ wọn. Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin. Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun, gbogbo irin ẹnu-ọ̀nà wọn ti di fífọ́.
31
Ìránṣẹ́ kan ń tẹ̀lé òmíràn láti sọ fún ọba Babeli pé gbogbo ìlú rẹ̀ ni a ti kó ní ìgbèkùn.
32
Odò tí ó sàn kọjá kò sàn mọ́ ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì.”
33
Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli sọ nìyìí: “Ọmọbìnrin Babeli dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options