Skip to content
Jeremiah 10:10-13

Jeremiah 10:10-13

10
Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́, òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé. Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì; orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.
11
“Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kéékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ”
12
Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀, ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.
13
Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo; ó mú kí ìkùùkuu ru sókè láti òpin ayé. Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options