Isaiah 61:8-11
8
“Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo; mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀. Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn.
9
A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”
10
Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa; ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi. Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo; gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà, àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.
11
Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jáde àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.
Settings