Skip to content
Isaiah 57:3-11

Isaiah 57:3-11

3
“Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ, ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè!
4
Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà? Ta ni o ń yọ ṣùtì sí tí o sì yọ ahọ́n síta? Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí, àti ìran àwọn òpùrọ́?
5
Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀; ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.
6
Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín; àwọ̀n ni ìpín in yín. Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀ àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun. Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ kí n dáwọ́ dúró?
7
Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà; níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.
8
Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí. Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀, ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada; ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn, ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn.
9
Ẹ̀yin lọ sí Moleki pẹ̀lú òróró olifi ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín. Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré; ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!
10
Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín, ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘Kò sí ìrètí mọ́?’ Ẹ rí okun kún agbára yín, nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín.
11
“Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù tí ẹ fi ń ṣèké sí mi, àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín? Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́ tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options