Skip to content
Isaiah 48:6-11

Isaiah 48:6-11

6
Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn. Ǹjẹ́ o kò nígbà wọ́n bí? “Láti ìsinsin yìí lọ, Èmi yóò máa sọ fún ọ nípa nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó fi ara sin tí ìwọ kò mọ̀.
7
A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́ ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní. Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’
8
Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bí láti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà. Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó; a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.
9
Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró; nítorí ìyìn ara mi, mo fà á sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ, kí a má ba à ké ọ kúrò.
10
Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí i fàdákà; Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.
11
Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí. Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́. Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options