Isaiah 45:9-13
9
“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà, ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀. Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé: ‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’ Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé, ‘Òun kò ní ọwọ́?’
10
Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Kí ni o bí?’ tàbí sí ìyá rẹ̀, ‘Kí ni ìwọ ti bí?’
11
“Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Nípa ohun tí ó ń bọ̀, ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi, tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?
12
Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀. Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run; mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta.
13
Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi. Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́. Òun yóò tún ìlú mi kọ́ yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
Settings