Isaiah 38:16-20
16
Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé; àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú wọn pẹ̀lú. Ìwọ dá ìlera mi padà kí o sì jẹ́ kí n wà láààyè.
17
Nítòótọ́ fún àlàáfíà ara mi ni, ní ti pé mo ní ìkorò ńlá. Nínú ìfẹ́ rẹ ìwọ pa mí mọ́, kúrò nínú ọ̀gbun ìparun; ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.
18
Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́, ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ; àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.
19
Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí; àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.
20
Olúwa yóò gbà mí là bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókùn ní gbogbo ọjọ́ ayé wa nínú tẹmpili ti Olúwa.
Settings