Isaiah 10:13-17
13
Nítorí ó sọ pé: “ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye. Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, mo sì ti kó ìṣúra wọn. Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.
14
Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè kò sí èyí tí ó fi apá lu apá, tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”
15
Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í, tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó? Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè, tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.
16
Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí àwọn akíkanjú jagunjagun, lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.
17
Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná, Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná, ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.
Settings