Hosea 4:6-8
6
àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀. “Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀. Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi; nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀, Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.
7
Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú
8
wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi, wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.
Settings