Heberu 10:5-10
5
Nítorí náà nígbà tí Kristi wá sí ayé, ó wí pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ, ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi,
6
ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò ní inú dídùn sí.
7
Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsi i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọ ọ́ nípa ti èmi) mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ”
8
Nígbà tí o wí ni ìṣáájú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin).
9
Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsi i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” Ó mú ti ìṣáájú kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀.
10
Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.
Settings