Skip to content
Esra 9:5-9

Esra 9:5-9

5
Ní ìgbà tí ó di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, mo dìde kúrò nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mi, pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi yíya ní ọrùn mi, mo kúnlẹ̀ lórí eékún mi méjèèjì, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi méjèèjì sí Olúwa Ọlọ́run mi.
6
Mo sì gbàdúrà: “Ojú tì mí gidigidi, tí n kò fi lè gbé ojú mi sókè sí ọ̀dọ̀ rẹ, Ọlọ́run mi, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá di púpọ̀ ní orí wa, ẹ̀bi wa sì ga kan àwọn ọ̀run.
7
Láti ọjọ́ àwọn baba wá ni ẹ̀bi wa ti pọ̀ jọjọ títí di ìsinsin yìí. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwa àti àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa ni a ti sọ di ẹni idà, ẹni ìgbèkùn, ìkógun àti ẹni ẹ̀sín lọ́wọ́ àwọn àjèjì ọba, bí ó ti rí lónìí.
8
“Ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí, fún ìgbà díẹ̀, ni a ti fi oore-ọ̀fẹ́ fún wa láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa wá láti sálà, àti láti fi èèkàn fún wa ni ibi mímọ́ rẹ̀, nítorí kí Ọlọ́run kí ó lè mú ojú wa mọ́lẹ̀, kí ó sì tún wa gbé dìde díẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn wa.
9
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa jẹ́ ẹrú, Ọlọ́run wa kò fi wa sílẹ̀ nínú ìgbèkùn wa. Ó ti fi àánú hàn fún wa ni iwájú àwọn ọba Persia: Ó ti fún wa ní ìgbé ayé tuntun láti tún odi ilé Ọlọ́run wa mọ, kí a sì tún àwókù rẹ̀ ṣe, ó sì fi odi ààbò fún wa ní Juda àti ní Jerusalẹmu.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options