Esekiẹli 8:1-8
1
Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹfà ọdún kẹfà bí mo ṣe jókòó nílé mi pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Juda níwájú mi, ọwọ́ Olúwa Olódùmarè bà lé mi níbẹ̀.
2
Nígbà tí mo wò, mo rí ohun kan tí ó jọ ènìyàn. Láti ibi ìbàdí rẹ lọ sísàlẹ̀ dàbí iná, láti ibi ìbàdí yìí sókè sì mọ́lẹ̀ bí idẹ tó ń kọ mọ̀nà.
3
Ó na ohun tó dàbí ọwọ́ jáde, ó fi gba mi ní irun orí mú, Ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede-méjì ayé àti ọ̀run, ó sì mú mi lọ rí ìran Ọlọ́run, mo sì lọ sí Jerusalẹmu, ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òde àríwá níbi tí ère owú tí ó ń mú ni bínú wá níwájú mi.
4
Sì kíyèsi i, ògo Ọlọ́run Israẹli wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìran ti mo rí ni pẹ̀tẹ́lẹ̀.
5
Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá.” Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu-ọ̀nà ibi pẹpẹ.
6
Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra ńlá tí ilé Israẹli ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù èyí lọ.”
7
Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá. Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri.
8
Nígbà náà ló sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà,” nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan.
Settings