Esekiẹli 7:10-13
10
“ ‘Ọjọ́ náà dé! Kíyèsi ó ti dé! Ìparun ti bú jáde, ọ̀pá ti tanná, ìgbéraga ti rúdí!
11
Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú; ọ̀pá láti jẹ ẹni búburú ní ìyà. Kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kù, tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, kò sí nínú ọrọ̀ wọn, kò sí ohun tí ó ní iye.
12
Àkókò náà dé! Ọjọ́ náà ti dé! Kí òǹrajà má ṣe yọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ki òǹtajà má ṣe ṣọ̀fọ̀; nítorí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.
13
Nítorí pé òǹtajà kì yóò rí gbà padà dúkìá èyí tó tà níwọ̀n ìgbà ti àwọn méjèèjì bá wà láààyè. Nítorí ìran tó kan gbogbo ènìyàn yìí kò ní yí padà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò gba ara rẹ̀ là.
Settings