Esekiẹli 48:30-33
30
“Ìwọ̀nyí ní yóò jẹ́ ẹnu-ọ̀nà àbájáde ìlú ńlá náà: “Bẹ̀rẹ̀ láti ìhà àríwá, ti ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn,
31
ẹnu-ọ̀nà ìlú ńlá náà ní àwa yóò fi orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli pè. Àwọn ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ìhà àríwá ní yóò jẹ́ ọ̀nà tí Reubeni, ọ̀nà tí Juda ọ̀nà tí Lefi.
32
Ní ìhà ìlà-oòrùn, èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ni ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ọ̀nà Josẹfu, ọ̀nà tí Benjamini àti ọ̀nà tí Dani.
33
Ní ìhà gúúsù, èyí tí wíwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ní ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ojú ọ̀nà Simeoni, ojú ọ̀nà Isakari àti ojú ọ̀nà Sebuluni.
Settings