Esekiẹli 46:9-12
9
“ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá síwájú Olúwa ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù wọlé yóò gba tí ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé jáde, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu-ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde.
10
Ọmọ-aládé gbọdọ̀ wà ní àárín wọn, kí ó wọlé nígbà tí wọn bá wọlé, kí ó sì jáde nígbà tí wọn bá jáde.
11
“ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ efa kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù kan, efa kan fún àgbò kan, àti fún àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá ti wu onílúlùkù, pẹ̀lú òróró hínì kan fún efa kan.
12
Nígbà tí ọmọ-aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí ó wà ni ṣíṣí sílẹ̀ fún un. Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, òun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu-ọ̀nà.
Settings