Skip to content
Esekiẹli 34:25-27

Esekiẹli 34:25-27

25
“ ‘Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, èmi yóò sì gba ilẹ̀ náà kúrò lọ́wọ́ ẹranko búburú, kí wọn kí o lè gbé ní aṣálẹ̀, kí àgùntàn sì gbé ní inú igbó ní àìléwu.
26
Èmi yóò bùkún wọn àti ibi agbègbè ti ó yí òkè mi ká. Èmi yóò rán ọ̀wààrà òjò ni àkókò; òjò ìbùkún yóò sì wà.
27
Àwọn igi igbó yóò mú èso wọn jáde, ilẹ̀ yóò sì mu irúgbìn jáde; A yóò sì dá ààbò bo àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ náà. Wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá já àwọn ohun tí ó ṣe okùnfà àjàgà, tí mo sì gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó fi wọ́n ṣe ẹrú.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options