Esekiẹli 34:17-22
17
“ ‘Ní tìrẹ, agbo ẹran mi, èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn kan àti òmíràn, àti láàrín àgbò àti ewúrẹ́.
18
Ṣé oúnjẹ jíjẹ ní pápá oko tútù dídára kò tó yín! Ṣé ó jẹ́ dandan fún ọ láti fi ẹsẹ̀ tẹ pápá oko tútù rẹ tí ó kù? Ṣé omi tí ó tòrò kò tó fún yín ní mímu? Ṣe dandan ni kí ó fi ẹrẹ̀ yí ẹsẹ̀ yín?
19
Ṣé dandan ni kí agbo ẹran mi jẹ́ koríko tí ẹ ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọn sì mú omi tí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ wọn sọ di ẹrẹ̀?
20
“ ‘Nítorí náà, èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí fún wọn: Wò ó, èmi fúnra mi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn tí ó sanra àti èyí tí ó rù.
21
Nítorí ti ìwọ sún síwájú pẹ̀lú ìhà àti èjìká, tí ìwọ sì kan aláìlágbára àgùntàn pẹ̀lú ìwo rẹ títí ìwọ fi lé wọn lọ,
22
Èmi yóò gba agbo ẹran mi là, a kì yóò sì kò wọ́n tì mọ́. Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn kan àti òmíràn.
Settings