Esekiẹli 31:1-5
1
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹta ọdún kọkànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2
“Ọmọ ènìyàn, sọ fún Farao ọba Ejibiti àti sí ìjọ rẹ̀: “ ‘Ta ní a le fiwé ọ ní ọláńlá?
3
Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni Lebanoni ní ìgbà kan rí, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà; tí ó ga sókè, òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.
4
Omi mú un dàgbàsókè: orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè; àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká, ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.
5
Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío ju gbogbo igi orí pápá lọ; ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn, wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
Settings