Skip to content
Esekiẹli 29:1-9

Esekiẹli 29:1-9

1
Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
2
“Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti.
3
Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ. Èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”
4
Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ. Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ, àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
5
Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ: ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè. Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.
6
Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé, Èmi ni Olúwa. “ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli.
7
Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.
8
“ ‘Nítorí náà, èyí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi, Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ.
9
Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa. “ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili, Èmi ni mo ṣe é,”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options