Skip to content
Esekiẹli 28:24-26

Esekiẹli 28:24-26

24
“ ‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.
25
“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu.
26
Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígbà tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi ṣẹ̀ sí ara àwọn tí ń ṣátá wọn ní gbogbo àyíká wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options