Skip to content
Esekiẹli 26:15-17

Esekiẹli 26:15-17

15
“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Tire: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń ṣẹlẹ̀ ní inú rẹ?
16
Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ-aládé etí Òkun yóò sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn da, tì wọn yóò sì bọ́ àwọn aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jókòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́.
17
Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé: “ ‘Báwo ni a ṣe pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkí ìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀! Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogbo òun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; ìwọ gbé ẹ̀rù rẹ lórí gbogbo olùgbé ibẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options