Esekiẹli 20:13-24
13
“ ‘Síbẹ̀; ilé Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí mí nínú aginjù. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, èmi yóò sì pa wọ́n run nínú aginjù.
14
Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní mú kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo kó wọn jáde.
15
Nítorí náà, mo tún gbọ́wọ́ mi sókè ní ìbúra fún wọn nínú aginjù pé, èmi kì yóò mú wọn dé ilẹ̀ tí mo fi fún wọn—ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù.
16
Nítorí pé, wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́. Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn.
17
Síbẹ̀síbẹ̀ mo wò wọ́n pẹ̀lú àánú, ń kò sì pa wọ́n run tàbí kí òpin dé bá wọn nínú aginjù.
18
Ṣùgbọ́n mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú aginjù pé, “Ẹ má ṣe rìn ní ìlànà àwọn baba yín, ẹ má ṣe pa òfin wọn mọ́, ẹ má ṣe bá ara yín jẹ́ pẹ̀lú òrìṣà wọn.
19
Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ó sì pa òfin mi mọ́.
20
Ẹ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́ kí ó lè jẹ́ àmì láàrín wa, ki ẹ lè mọ̀ pé èmi ní Olúwa Ọlọ́run yín.”
21
“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn kò sì pa òfin mi mọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá tẹ̀lé àwọn òfin yìí, yóò yè nínú rẹ̀, wọ́n sì tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú mi lórí wọn, Èmi yóò sì mú kí ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn ni aginjù.
22
Síbẹ̀síbẹ̀ mo dáwọ́ dúró, nítorí orúkọ mi, mo sì ṣe ohun tí kò ní ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè ti mo kó wọn jáde lójú wọn.
23
Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú ọwọ́ ti mo gbé sókè sí wọn, mo búra fún wọn nínú aginjù pé èmi yóò tú wọn ka sì àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ gbogbo,
24
nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, wọn sì tún kọ àṣẹ mi sílẹ̀, wọn tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Ojú wọn sì wà ní ara òrìṣà baba wọn.
Settings