Esekiẹli 18:2-4
2
“Kín ni ẹ̀yin rò tí ẹ̀yin fi ń pa òwe nípa Israẹli wí pé: “ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà kíkan, eyín àwọn ọmọ sì kan.’
3
“Bí mo ti wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, ẹ̀yin kí yóò pa òwe yìí mọ́ ni Israẹli.
4
Nítorí pé èmi ló ní gbogbo ọkàn, ọkàn baba tèmi bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ pàápàá jẹ tèmi, ọkàn tó bá ṣẹ̀ ní yóò kú.
Settings