Skip to content
Esekiẹli 11:13

Esekiẹli 11:13

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 13 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
10
Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.
11
Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli.
12
Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ̀yin kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.”
13
Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pelatiah ọmọ Benaiah kú. Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Ṣé ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli run pátápátá ni?”
14
Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé,
15
“Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Israẹli pátápátá, ni àwọn ará Jerusalẹmu ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà sí Olúwa, àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní.’
16
“Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀-èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, èmi yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options