Eksodu 6:18-22
18
Àwọn ọmọ Kohati ni: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli. Kohati lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé.
19
Àwọn ọmọ Merari ni: Mahili àti Muṣi. Ìwọ̀nyí ni ìran Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn.
20
Amramu sì fẹ́ Jokebedi arábìnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jokebedi sì bí Aaroni àti Mose fún un. Amramu lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.
21
Àwọn ọmọ Isari ni: Kora, Nefegi àti Sikri.
22
Àwọn ọmọ Usieli ni: Miṣaeli, Elsafani àti Sitiri.
Settings