Eksodu 34:10
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 10 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
7
Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1,000), ó sì ń dáríjì àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń ṣọ̀tẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.”
8
Mose foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì sìn.
9
Ó wí pé, “Olúwa, bí èmi bá rí ojúrere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí Olúwa lọ pẹ̀lú wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ.”
10
Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èmi dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú yín. Níwájú gbogbo ènìyàn rẹ Èmi yóò ṣe ìyanu, tí a kò tí ì ṣe ní orílẹ̀-èdè ní gbogbo ayé rí. Àwọn ènìyàn tí ìwọ ń gbé láàrín wọn yóò rí i bí iṣẹ́ tí Èmi Olúwa yóò ṣe fún ọ ti ní ẹ̀rù tó.
11
Ṣe ohun tí Èmi pàṣẹ fún ọ lónìí. Èmi lé àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde níwájú rẹ.
12
Máa ṣọ́ra kí o má ba à bá àwọn ti ó n gbé ilẹ̀ náà tí ìwọ ń lọ dá májẹ̀mú, nítorí wọn yóò jẹ́ ìdẹwò láàrín rẹ.
13
Wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, fọ́ òkúta mímọ́ wọn, kí o sì gé òpó Aṣerah wọn. (Ère òrìṣà wọn.)
Settings