Eksodu 30:1-6
1
“Ìwọ yóò sì ṣe pẹpẹ igi kasia kan; máa jó tùràrí lórí rẹ̀.
2
Kí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé, kí ó jẹ́ ìdajì mita ní gígùn, ìdajì mita ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga rẹ̀—kí ìwo rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
3
Ìwọ yóò sì bo òkè rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀ pẹ̀lú u kìkì wúrà, ìwọ yóò sì ṣe wúrà gbà á yíká.
4
Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì fún pẹpẹ náà níṣàlẹ̀ ìgbátí méjèèjì ní òdìkejì ìhà rẹ̀—láti gbá àwọn òpó rẹ̀ mú, láti lè máa fi gbé e.
5
Ìwọ yóò sì ṣe òpó igi kasia, ìwọ yóò sì bọ́ wọ́n pẹ̀lú wúrà.
6
Ìwọ yóò gbé pẹpẹ náà sí iwájú aṣọ ìkélé, èyí tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí níwájú ìtẹ́ àánú èyí tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí níbi ti èmi yóò ti máa bá ọ pàdé.
Settings