Eksodu 29:38-46
38
“Èyí ni ìwọ yóò máa fi rú ẹbọ ní orí pẹpẹ náà: Ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan ni ojoojúmọ́ láéláé.
39
Ọ̀dọ́-àgùntàn kan ni ìwọ yóò fi rú ẹbọ ní òwúrọ̀ àti ọ̀dọ́-àgùntàn èkejì ní àṣálẹ́.
40
Pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn ti àkọ́kọ́ rú ẹbọ ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára tí a fi ìdámẹ́rin hínì òróró lára olifi tí a gún, àti ìdámẹ́rin hínì wáìnì bí ẹbọ mímu.
41
Ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ni kí ìwọ kí ó pa rú ẹbọ ní àṣálẹ́ ìwọ yóò sì ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu bí ti òwúrọ̀ fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe ni sí Olúwa.
42
“Fún ìrandíran tó ń bọ̀, ni ẹ ó máa ṣe ẹbọ sísun nígbà gbogbo ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ níwájú Olúwa. Níbẹ̀ èmi yóò pàdé yín, èmi yóò sì bá a yín sọ̀rọ̀;
43
níbẹ̀ sì tún ni èmi yóò pàdé àwọn ọmọ Israẹli, a ó sì fi ògo mi ya àgọ́ náà sí mímọ́.
44
“Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ya àgọ́ àjọ náà sí mímọ́ àti pẹpẹ náà, èmi yóò sì ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ bí àlùfáà fún mi.
45
Nígbà náà ni èmi yóò máa gbé láàrín àwọn ọmọ Israẹli, èmi yóò sì máa ṣe Ọlọ́run wọn.
46
Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, nítorí kí èmi lè máa gbé àárín wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.
Settings