Eksodu 25:31-40
31
“Ìwọ ó sì ojúlówó wúrà, lù ú dáradára, ṣe ọ̀pá fìtílà kan, ìsàlẹ̀ àti apá rẹ̀, kọ́ọ̀bù rẹ̀ ti ó dàbí òdòdó, ìṣọ àti ìtànná rẹ̀ yóò jẹ́ ara kan náà pẹ̀lú rẹ̀.
32
Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì.
33
Àwo mẹ́ta ni kí a ṣe bí ìtànná almondi, tí ó ṣọ tí ó sì tanná ni yóò wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta yóò sì wà ní ẹ̀ka kejì, àti bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó jáde lára ọ̀pá fìtílà.
34
Ní ara ọ̀pá fìtílà ni àwo mẹ́rin ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí òdòdó almondi ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà.
35
Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta, ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀.
36
Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà.
37
“Nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe fìtílà méje. Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn kí ó lè máa ṣe ìmọ́lẹ̀ sí iwájú rẹ̀.
38
Àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alimagaji rẹ̀, kí ó jẹ́ kìkì wúrà.
39
Tálẹ́ǹtì kìkì wúrà ni ó fi ṣe é, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọ̀nyí.
40
Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.
Settings