Skip to content
Eksodu 18:13-18

Eksodu 18:13-18

13
Ní ọjọ́ kejì, Mose jókòó láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀; àwọn ènìyàn sì dúró ti Mose fún ìdájọ́ wọn láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.
14
Nígbà tí àna Mose rí bí àkókò ti èyí ń gba ti pọ̀ tó àti ti àwọn ènìyàn ti ń dúró pẹ́ tó, ó wí pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ń ṣe sí àwọn ènìyàn? Èéṣe ti ìwọ nìkan jókòó gẹ́gẹ́ bí adájọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró yí ọ ká láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́?”
15
Mose dá a lóhùn pé, “Nítorí àwọn ènìyàn ń tọ̀ mí wá láti mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run.
16
Nígbà tí wọ́n bá ní ẹjọ́, wọn a mú un tọ̀ mí wá, èmi a sì ṣe ìdájọ́ láàrín ẹnìkínní àti ẹnìkejì, èmi a sì máa mú wọn mọ òfin àti ìlànà Ọlọ́run.”
17
Àna Mose dá a lóhùn pé, “Ohun tí o ń ṣe yìí kò dára.
18
Ìwọ àti àwọn ènìyàn ti ń tọ̀ ọ́ wá yìí yóò dá ara yín ní agara; iṣẹ́ yìí pọ̀jù fún ọ, ìwọ nìkan kò lè dá a ṣe.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options