Skip to content
Deuteronomi 9:8-21

Deuteronomi 9:8-21

8
Ní Horebu ẹ̀yin ti mú kí Olúwa bínú, títí dé bi pé ó fẹ́ run yín.
9
Nígbà tí mo gòkè lọ láti lọ gba wàláà òkúta, wàláà májẹ̀mú ti Olúwa ti bá a yín dá. Ogójì ọ̀sán àti òru ni mo fi wà lórí òkè náà, èmi kò fẹnu kan oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni ń kò mu omi.
10
Olúwa fún mi ní wàláà òkúta méjì tí a fi ìka Ọlọ́run kọ. Lórí wọn ni a kọ àwọn òfin tí Ọlọ́run sọ fún un yín lórí òkè láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀ sí.
11
Lópin ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí, Olúwa fún mi ní sílétì òkúta méjì, wàláà òkúta májẹ̀mú náà.
12
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìn-ín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Ejibiti ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kúrò, nínú ọ̀nà mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.”
13
Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle gbá à ni wọ́n.
14
Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀jù wọ́n lọ.”
15
Báyìí ni mo yípadà, tí mó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá, orí òkè tí o ń yọ iná. Àwọn wàláà májẹ̀mú méjèèjì sì wà lọ́wọ́ mi.
16
Ìgbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín. Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un yín.
17
Bẹ́ẹ̀ ni mó ju wàláà méjèèjì náà mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ lójú u yín.
18
Lẹ́yìn náà mo tún wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi kò jẹ oúnjẹ kankan bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu omi, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ tí dá, tí ẹ sì ń ṣe búburú lójú Olúwa, tí ẹ sì ń mú u bínú.
19
Mo bẹ̀rù ìbínú àti ìrunú Olúwa, nítorí pé inú bí i sí i yín dé bi wí pé ó fẹ́ pa yín run. Ṣùgbọ́n Olúwa tún fetí sí mi lẹ́ẹ̀kan sí i.
20
Inú sì bí Olúwa sí Aaroni láti pa á run, nígbà náà ni mo tún gbàdúrà fún Aaroni náà.
21
Bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú ohun tí ó mú un yín dẹ́ṣẹ̀, àní ère ẹgbọrọ màlúù tí ẹ ti ṣe, mo sì fi iná sun ún, bẹ́ẹ̀ ni mo gún un, mo sì lọ̀ ọ́ lúúlúú bí eruku lẹ́búlẹ́bú, mo sì da ẹ̀lọ̀ rẹ̀ sínú odò tí ń sàn nísàlẹ̀ òkè.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options