Skip to content
Deuteronomi 9:7

Deuteronomi 9:7

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 7 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
4
Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti lé wọn jáde níwájú u yín, ẹ má ṣe wí fún ara yín pé, “Torí òdodo mi ní Olúwa ṣe mú mi wá síbí láti gba ilẹ̀ náà.” Rárá, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Olúwa yóò ṣe lé wọn jáde níwájú u yín.
5
Kì í ṣe nítorí òdodo yín, tàbí ìdúró ṣinṣin ni ẹ ó fi wọ ìlú wọn lọ láti gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi lé wọn jáde kúrò níwájú u yín láti lè mú ohun tí ó búra fún àwọn baba ṣẹ: fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.
6
Ṣùgbọ́n kí ó yé yín pé kì í ṣe nítorí òdodo yín ni Olúwa Ọlọ́run yín fi ń fún un yín ní ilẹ̀ rere náà, láti ní, nítorí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ jẹ́.
7
Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ̀yin ti mú Olúwa Ọlọ́run yín bínú ní aginjù. Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Ejibiti ni ẹ̀yin ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa títí tí ẹ̀yin fi dé ìhín yìí.
8
Ní Horebu ẹ̀yin ti mú kí Olúwa bínú, títí dé bi pé ó fẹ́ run yín.
9
Nígbà tí mo gòkè lọ láti lọ gba wàláà òkúta, wàláà májẹ̀mú ti Olúwa ti bá a yín dá. Ogójì ọ̀sán àti òru ni mo fi wà lórí òkè náà, èmi kò fẹnu kan oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni ń kò mu omi.
10
Olúwa fún mi ní wàláà òkúta méjì tí a fi ìka Ọlọ́run kọ. Lórí wọn ni a kọ àwọn òfin tí Ọlọ́run sọ fún un yín lórí òkè láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀ sí.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options