Skip to content
Daniẹli 3:1-7

Daniẹli 3:1-7

1
Nebukadnessari ọba gbẹ́ ère wúrà kan, èyí tí gíga rẹ̀ tó àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ tó ẹsẹ̀ mẹ́fà, ó sì gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura ní agbègbè ìjọba Babeli.
2
Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn ìgbìmọ̀, àwọn baálẹ̀, àwọn balógun, àwọn onídàájọ́, àwọn olùtọ́jú ìṣúra àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba láti wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀.
3
Nígbà náà ni àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn onímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba, wọn péjọ láti ya ère tí Nebukadnessari ọba gbé kalẹ̀ sí mímọ́, gbogbo wọn sì dúró síwájú u rẹ̀.
4
Nígbà náà ni a kéde kígbe sókè wí pé, “Ohun tí a paláṣẹ fún un yín láti ṣe nìyìí, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo.
5
Bí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò, kí ẹ wólẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀.
6
Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ tí kò bá wólẹ̀, kí ó fi orí balẹ̀, kí a ju ẹni náà sínú iná ìléru.”
7
Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options