Ìṣe àwọn Aposteli 13:42-44
42
Bí Paulu àti Barnaba sì ti ń jáde láti inú Sinagọgu, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀.
43
Nígbà tí wọn sì jáde nínú Sinagọgu, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀lé Paulu àti Barnaba, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
44
Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ péjọ tan láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
Settings