2 Samuẹli 18:9-15
9
Absalomu sì pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dafidi. Absalomu sì gun orí ìbáaka kan, ìbáaka náà sì gba abẹ́ ẹ̀ka ńlá igi óákù kan tí ó tóbi lọ, orí rẹ̀ sì kọ́ igi óákù náà òun sì rọ̀ sókè ní agbede-méjì ọ̀run àti ilẹ̀; ìbáaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sì lọ kúrò.
10
Ọkùnrin kan sì rí i, ó sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, èmi rí Absalomu so rọ̀ láàrín igi óákù kan.”
11
Joabu sì wí fún ọkùnrin náà tí ó sọ fún un pé, “Sá wò ó, ìwọ rí i, èéha ti ṣe tí ìwọ kò fi lù ú bolẹ̀ níbẹ̀? Èmi ìbá sì fún ọ ní ṣékélì fàdákà mẹ́wàá, àti àmùrè kan.”
12
Ọkùnrin náà sì wí fún Joabu pé, “Bí èmi tilẹ̀ gba ẹgbẹ̀rún (1,000) ṣékélì fàdákà sí ọwọ́ mí, èmi kì yóò fi ọwọ́ mi kan ọmọ ọba, nítorí pé àwa gbọ́ nígbà tí ọba kìlọ̀ fún ìwọ àti Abiṣai, àti Ittai, pé, ‘Ẹ kíyèsi i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọwọ́ kan ọ̀dọ́mọkùnrin náà Absalomu.’
13
Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ èmi ìbá ṣe sí ara mi, nítorí pé kò sí ọ̀ràn kan tí ó pamọ́ fún ọba, ìwọ tìkára rẹ̀ ìbá sì kọjú ìjà sí mi pẹ̀lú.”
14
Joabu sì wí pé, “Èmi kì yóò dúró bẹ́ẹ̀ níwájú rẹ.” Ó sì mú ọ̀kọ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ́n gún Absalomu ní ọkàn, nígbà tí ó sì wà láààyè ní agbede-méjì igi óákù náà.
15
Àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin mẹ́wàá tí ó máa ń ru ìhámọ́ra Joabu sì yí Absalomu ká, wọ́n sì kọlù ú, wọ́n sì pa á.
Settings