2 Ọba 12:5-8
5
Jẹ́ kí gbogbo àlùfáà gba owó náà lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwọn akápò. Kí a sì lò ó fún tuntun ohunkóhun tí ó bá bàjẹ́ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.”
6
Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹtàlélógún ọba Jehoaṣi, àwọn àlùfáà kò ì tí ì tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.
7
Nígbà náà, ọba Jehoaṣi pe Jehoiada àlùfáà àti àwọn àlùfáà yòókù, ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tún ìbàjẹ́ tí a ṣe sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe? Ẹ má ṣe gba owó mọ́ lọ́wọ́ àwọn afowópamọ́, ṣùgbọ́n ẹ gbé e kalẹ̀ fún títún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.”
8
Àwọn àlùfáà fi ara mọ́ pé wọn kò nígbà owó kankan mọ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sì ni, wọn kò sì ní tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe mọ́ fúnra wọn.
Settings