1 Ọba 21:17-24
17
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah ará Tiṣibi wá wí pé,
18
“Sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ pàdé Ahabu ọba Israẹli, tí ó wà ní Samaria. Ó wà ní ọgbà àjàrà Naboti báyìí, níbi tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún rẹ̀.
19
Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Naboti, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ”
20
Ahabu sì wí fún Elijah pé, “Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀tá mi!” Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú Olúwa.
21
‘Èmi yóò mú ibi wá sórí rẹ. Èmi yóò sì mú ìran rẹ kúrò, èmi yóò sì ké kúrò lọ́dọ̀ Ahabu gbogbo ọmọdé ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀, àti òmìnira ní Israẹli.
22
Èmi yóò ṣe ilé rẹ bí ilé Jeroboamu, ọmọ Nebati, àti bí ilé Baaṣa, ọmọ Ahijah, nítorí ìwọ ti mú mi bínú, ìwọ sì ti mú Israẹli ṣẹ̀.’
23
“Àti ní ti Jesebeli pẹ̀lú Olúwa wí pé, ‘Àwọn ajá yóò jẹ Jesebeli nínú yàrá Jesreeli.’
24
“Àwọn ajá yóò jẹ ẹni Ahabu tí ó kú ní ìlú, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ àwọn ẹni tí ó kú ní igbó.”
Settings