1 Kọrinti 13:8-10
8
Ìfẹ́ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bùn ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.
9
Nítorí àwa mọ̀ ní apá kan, àwa sì sọtẹ́lẹ̀ ní apá kan.
10
Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí ti o pé bá dé, èyí tí í ṣe tí apá kan yóò dópin.