Skip to content
1 Kronika 26:10-19

1 Kronika 26:10-19

10
Hosa ará Merari ní àwọn ọmọkùnrin: Ṣimri alákọ́kọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kì i ṣe àkọ́bí, baba a rẹ̀ ti yàn an ní àkọ́kọ́.
11
Hilkiah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tabaliah ẹ̀kẹta àti Sekariah ẹ̀kẹrin. Àwọn ọmọ àti ìbátan Hosa jẹ́ mẹ́tàlá ni gbogbo rẹ̀.
12
Ìpín wọ̀nyí ti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà nípasẹ̀ olóyè ọkùnrin wọn, ní iṣẹ́ ìsìn fún jíjíṣẹ́ nínú ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìbátan wọn ti ṣe.
13
Wọ́n ṣẹ́ kèké fún ẹnu-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ìdílé wọn bí ọ̀dọ́ àti arúgbó.
14
Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ilà oòrùn bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣelemiah. Nígbà náà a dá kèké fún ọmọkùnrin rẹ̀ Sekariah, ọlọ́gbọ́n onímọ̀ràn, kèké fún ẹnu-ọ̀nà àríwá sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
15
Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù bọ́ sí ọ̀dọ̀ Obedi-Edomu, kèké fún ilé ìṣúra sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ ọmọ rẹ̀.
16
Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣaleketi ẹnu-ọ̀nà ní ọ̀nà apá òkè bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣuppimu àti Hosa. Olùṣọ́ wà ní ẹ̀bá olùṣọ́.
17
Àwọn ará Lefi mẹ́fà ní ó wà ní ọjọ́ kan ní ìhà ìlà-oòrùn, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà àríwá, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà gúúsù àti méjì ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ilé ìṣúra.
18
Ní ti ilé ẹjọ́ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, mẹ́rin sì wà ní ojú ọ̀nà àti méjì ní ilé ẹjọ́ fúnra rẹ̀.
19
Wọ̀nyí ni ìpín ti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àwọn ìran ọmọ Kora àti Merari.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options